Use your preferred language to learn new language


Reading Yorùbá numerals from zero (0) to one hundred (100)

Reading Yorùbá numerals from zero (0) to one hundred (100)

Kíka òǹkà Yorùbá láti oódo (0) sí ọgọ́rùn-ún (100)

0 - Zero

 0 - Oódo

1 - One
 

 1 - Oókan

2 - Two
 

 2 - Eéjì

3 - Three

 3 – Ẹẹ́ta

4 - Four

 4 - Ẹẹ́rin

5 - Five

 5 - Aárùn-ún

6 - Six

 6 - Ẹẹ́fà

7 - Seven

 7 - Eéje

8 - Eight 8 - Ẹẹ́jọ
9 - Nine 9 - Ẹẹ́sàn-án
10 - Ten

 10 - Ẹẹ́wàá

11 - Eleven

 11 – Oókànlá

12 - Twelve

12 – Eéjìlá  

13 - Thirteen

13 – Ẹẹ́tàlá  

14 - Fourteen

14 – Ẹẹ́rìnlá   

15 - Fifteen 15 - Aárùndínlógún (20 - 5 = 15)     

Note:

Aárùndínlógún (15) is a contraction of aárùn-ún (5) dín ní (-/minus) ogún (20).

 Kíyèsí:

Ìsúnkì aárùn-ún (5) dín ní (-) ogún (20) ni Aárùndínlógún (15) jẹ́.

This means that 20 – 5 = 15.

 Èyí túnmọ̀ sí wípé 20 – 5 = 15.

   

Note:

The numbers from 15 to 19 are derived by respectively subtracting (-/minus) 5, 4, 3, 2, and 1 from twenty (20).

Kíyèsí:

Nípasẹ̀ ìyọkúrò (-) àwọn nọ́mbà 5, 4, 3, 2 àti 1 lẹ́sẹẹsẹ láti ara nọ́mbà ogún (20) ni a ṣe máa ń ṣe ẹ̀dá àwọn nọ́mbà tí ó wà láti orí 15 sí 19.

Example:

20 – 5 = 15

Àpẹrẹ:

20 – 5 = 15

20 – 4 = 16 20 – 4 = 16
20 – 3 = 17

20 – 3 = 17

20 – 2 = 18 20 – 2 = 18
20 – 1 = 19

 20 – 1 = 19

16 - Sixteen 16 - Ẹẹ́rìndínlógún (20 - 4 = 16)

Note:

Ẹẹ́rìndínlógún (16) is a contraction of Ẹẹ́rin (4) dín ní (-/minus) ogún (20).

 Kíyèsí:

Ìsúnkì Ẹẹ́rin (4) dín ní (-) ogún (20) ni Ẹẹ́rìndínlógún (16) jẹ́.

This means that 20 – 4 = 16. Èyí túnmọ̀ sí wípé 20 – 4 = 16.
17 - Seventeen

 17 - Ẹẹ́tàdínlógún (20 - 3 = 17)

Note:

Ẹẹ́tàdínlógún (17) is a contraction of Ẹẹ́ta (3) dín ní (-/minus) ogún (20).

 Kíyèsí:

Ìsúnkì Ẹẹ́ta (3) dín ní (-) ogún (20) ni Ẹẹ́tàdínlógún (17) jẹ́.

This means that 20 – 3 = 17. Èyí túnmọ̀ sí wípé 20 – 3 = 17.
18 - Eighteen

 18 - Eéjìdínlógún (20 - 2 = 18)

Note:

Eéjìdínlógún (18) is a contraction of Eéjì (2) dín ní (-/minus) ogún (20).

 Kíyèsí:

Ìsúnkì Eéjì (2) dín ní (-) ogún (20) ni Eéjìdínlógún (18) jẹ́.

That means that 20 – 2 = 18.

 Èyí túnmọ̀ sí wípé 20 – 2 = 18.

19 – Nineteen

 19 - Oókàndínlógún (20 - 1 = 19)

Note:

Oókàndínlógún (19) is a contraction of Oókan (1) dín ní (-/minus) ogún (20).

 Kíyèsí:

Ìsúnkì Oókan (1) dín ní (-) ogún (20) ni Oókàndínlógún (19) jẹ́.

This means that 20 – 1 = 19.

Èyí túnmọ̀ sí wípé 20 – 1 = 19.

20 – Twenty

 20 – Ogún

Note:

The numbers from 21 to 24 are derived by respectively adding (+) 1, 2, 3, and 4 to twenty (20).

Kíyèsí:

Nípasẹ̀ àfikún (+) àwọn nọ́mbà 1, 2, 3 àti 4 lẹ́sẹẹsẹ pẹ̀lú nọ́mbà ogún (20) ni a ṣe máa ń ṣe ẹ̀dá àwọn nọ́mbà tí ó wà láti orí 21 sí 24.

Example:

            20 + 1 = 21

 Àpẹrẹ:

            20 + 1 = 21

20 + 2 = 22

  20 + 2 = 22

   20 + 3 = 23    20 + 3 = 23
  20 + 4 = 24    20 + 4 = 24
Apply addition (+) from 21 to 24

 Lo àfikún (+) láti 21 sí 24

21 - Twenty-one

 21 - Oókànlélógún (20 + 1 = 21)

Note:

Oókànlélógún (21) is a contraction of Oókan (1) lé ní (+/adds) ogún (20).

 Kíyèsí:

Ìsúnkì Oókan (1) lé ní (+) ogún (20) ni Oókànlélógún (21) jẹ́.

This means that 20 + 1 = 21.

 Èyí túnmọ̀ sí wípé 20 + 1 = 21.

22 - Twenty-two

 22 - Eéjìlélógún (20 + 2 = 22)

Note:

Eéjìlélógún (22)  is a contraction of Eéjì (2) lé ní (+/adds) ogún (20).

Kíyèsí:

Ìsúnkì Eéjì (2) lé ní (+) ogún (20) ni Eéjìlélógún (22) jẹ́.

This means that 20 + 2 = 22.

 Èyí túnmọ̀ sí wípé 20 + 2 = 22.

23 - Twenty-three 23 - Ẹẹ́tàlélógún (20 + 3 = 23)

Note:

Ẹẹ́tàlélógún (23) is a contraction of Ẹẹ́ta (3) lé ní (+/adds) ogún (20).

Kíyèsí:

Ìsúnkì Ẹẹ́ta (3) lé ní (+) ogún (20) ni Ẹẹ́tàlélógún (23) jẹ́.

This means that 20 + 3 = 23.

 Èyí túnmọ̀ sí wípé 20 + 3 = 23.

24 - Twenty-four

 24 - Ẹẹ́rìnlélógún (20 + 4 = 24)

Note:

Ẹẹ́rìnlélógún (24) is a contraction of Ẹẹ́rin (4) lé ní (+/adds) ogún (20).

Kíyèsí:

Ìsúnkì Ẹẹ́rin (4) lé ní (+) ogún (20) ni Ẹẹ́rìnlélógún (24) jẹ́.

This means that 20 + 4 = 24.

Èyí túnmọ̀ sí wípé 20 + 4 = 24.

Apply subtraction (-) from 25 to 29

 Lo ìyọkúrò (-) láti 25 sí 29

25 - Twenty-Five

 25 – Aárùndínlọ́gbọ̀n (30 - 5 = 25)

Note:

Aárùndínlọ́gbọ̀n (25) is a contraction of Aárùn-ún (5) dín ní (-/minus) Ọgbọ̀n (30).

 Kíyèsí:

Ìsúnkì Aárùn-ún (5) dín ní (-) Ọgbọ̀n (30) ni Aárùndínlọ́gbọ̀n (25) jẹ́.

This means that 30 – 5 = 25.

 Èyí túnmọ̀ sí wípé 30 – 5 = 25.

26 - Twenty-six 26 - Ẹẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (30 - 4 = 26)

Note:

Ẹẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26) is a contraction of Ẹẹ́rin (4) dín ní (-/minus) Ọgbọ̀n (30).

 Kíyèsí:

Ìsúnkì Ẹẹ́rin (4) dín ní (-) Ọgbọ̀n (30) ni Ẹẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26) jẹ́.

This means that 30 – 4 = 26.

 Èyí túnmọ̀ sí wípé 30 – 4 = 26.

27 - Twenty-seven

27 - Ẹẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (30 - 3 = 27)

Note:

Ẹẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) is a contraction of Ẹẹ́ta (3) dín ní (-/minus) Ọgbọ̀n (30).

Kíyèsí:

Ìsúnkì Ẹẹ́ta (3) dín ní (-) Ọgbọ̀n (30) ni Ẹẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) jẹ́.

This means that 30 – 3 = 27.

 Èyí túnmọ̀ sí wípé 30 – 3 = 27.

28 - Twenty-eight 28 - Eéjìdínlọ́gbọ̀n (30 - 2 = 28)

Note:

Eéjìdínlọ́gbọ̀n (28) is a contraction of Eéjì (2) dín ní (-/minus) Ọgbọ̀n (30).

 Kíyèsí:

Ìsúnkì Eéjì (2) dín ní (-) Ọgbọ̀n (30) ni Eéjìdínlọ́gbọ̀n (28) jẹ́.

This means that 30 – 2 = 28.

Èyí túnmọ̀ sí wípé 30 – 2 = 28.

29 - Twenty-nine 29 - Oókàndínlọ́gbọ̀n (30 - 1 = 29)

Note:

Oókàndínlọ́gbọ̀n (29) is a contraction of oókan (1) dín ní (-/minus) Ọgbọ̀n (30).

 Kíyèsí:

Ìsúnkì oókan (1) dín ní (-) Ọgbọ̀n (30) ni Oókàndínlọ́gbọ̀n (29) jẹ́.

This means that 30 – 1 = 29.

Èyí túnmọ̀ sí wípé 30 – 1 = 29.

30 - Thirty

30 – Ọgbọ̀n

Apply addition (+) from 31 to 34 Lo àfikún (+) láti 31 sí 34
31 - Thirty-one

 31 – Oókànlélọ́gbọ̀n (30 + 1 = 31)

32 - Thirty-two

 32 - Eéjìlélọ́gbọ̀n (30 + 2 = 32)

33 - Thirty-three 33 - Ẹẹ́tàlélọ́gbọ̀n (30 + 3 = 33)

34 - Thirty-four

34 - Ẹẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (30 + 4 = 34)

Apply subtraction (-) from 35 to 39

 Lo ìyọkúrò (-) láti 35 sí 39

35 - Thirty-five

35 – Aárùndínlógójì

            (40 - 5 = 35)

36 - Thirty-six

36 – Ẹẹ́rìndínlógójì

            (40 – 4 + 36)

37 - Thrifty-seven

37 – Ẹẹ́tàdínlógójì

            (40 – 3 = 37)

38 - Thirty-eight

38 – Eéjìdínlógójì

            (40 – 2 = 38)

39 - Thirty-nine

39 – Oókàndínlógójì

            (40 – 1 + 39)

40 - Forty

40 – Ogójì

            (20 x 2 = 40)

Note:

Ogójì (40) is a contraction of ogún méjì (20 x 2).

 Kíyèsí:

Ìsúnkì Ogún méjì (20 x 2) ni Ogójì jẹ́.

Apply addition (+) from 41 to 44

 Lo àfikún (+) láti 41 sí 44

41 - Forty-one

 41 - Oókànlélógójì (40 + 1 = 41)

42 - Forty-two

 42 - Eéjìlélógójì (40 + 2 = 42)

43 - Forty-three

 43 - Ẹẹ́tàlélógójì (40 + 3 = 43)

44 - Forty-four

 44 - Ẹẹ́rìnlélógójì (40 + 4 = 44)

Apply subtraction (-) from 45 to 49

 Lo ìyọkúrò (-) láti 45 sí 49

45 - Forty-five

 45 – Aárùndínláàádọ́ta (50 – 5 + 45)

46 - Forty-six

 46 – Ẹẹ́rìndínláàádọ́ta (50 – 4 + 46)

47 - Forty-seven

 47 - Ẹẹ́tàdínláàádọ́ta (50 – 3 + 47)

48 - Forty-eight 48 - Eéjìdínláàádọ́ta (50 – 2 + 48)
49 - Forty-nine

 49 – Oókàndínláàádọ́ta (50 – 1 + 49)

50 – Fifty

 50 – Àádọ́ta (60 - 10 = 50)

Note:

Àádọ́ta (50) is a contraction of ẹẹ́wàá (10) dín ní (-/minus) ọgọ́ta (60).

 Kíyèsí:

Ìsúnkì ẹẹ́wàá (10) dín ní (-) ọgọ́ta (60) ni Àádọ́ta (50) jẹ́.

This means that 60 – 10 = 50. Èyí túnmọ̀ sí wípé 60 – 10 = 50.
Apply addition (+) from 51 to 54 Lo àfikún (+) láti 51 sí 54
51 - Fifty-one

 51 – Oókànléláàádọ́ta

52 - Fifty-two

 52 – Eéjìléláàádọ́ta

53 - Fifty-three 53 - Ẹẹ́tàléláàádọ́ta
54 - Fifty-four 54 - Ẹẹ́rìnléláàádọ́ta  
Apply subtraction (-) from 55 to 59

 Lo ìyọkúrò (-) láti 55 sí 59

55 - Fifty-five 55 - Aárùndínlọ́gọ́ta
56 - Fifty-six 56 - Ẹẹ́rìndínlọ́gọ́ta
57 - Fifty-seven 57 - Ẹẹ́tàdínlọ́gọ́ta
58 - Fifty-eight

 58 - Eéjìdínlọ́gọ́ta

59 - Fifty-nine

 59 - Oókàndínlọ́gọ́ta

60 - Sixty 60 – Ọgọ́ta (20 x 3)

Note:

Ọgọ́ta (60) is a contraction of ogún mẹ́ta (20 x 3).

 Kíyèsí:

Ìsúnkì Ogún mẹ́ta (20 x 3) ni Ọgọ́ta (60) jẹ́.

Apply addition (+) from 61 to 64

 Lo àfikún (+) láti 61 sí 64

61 - Sixty-one

 61 - Oókànlélọ́gọ́ta

62 - Sixty-two 62 - Eéjìlélọ́gọ́ta
63 - Sixty-three 63 - Ẹẹ́tàlélọ́gọ́ta
64 - Sixty-four

 64 - Ẹẹ́rìnlélọ́gọ́ta

Apply subtraction (-) from 65 to 69

 Lo ìyọkúrò (-) láti 65 sí 69

65 - Sixty-five

 65 - Aárùndínláàádọ́rin

66 - Sixty-six
 

 66 - Ẹẹ́rìndínláàádọ́rin

67 - Sixty-seven

 67 - Ẹẹ́tàdínláàádọ́rin

68 - Sixty-eight

 68 - Eéjìdínláàádọ́rin

69 - Sixty-nine 69 - Oókàndínláàádọ́rin
70 - Seventy 70 - Àádọ́rin (80 - 10)

Note:

Àádọ́rin (70) is a contraction of ẹẹ́wàá (10) dín ní (-/minus) Ọgọ́rin (80).

 Kíyèsí:

Ìsúnkì ẹẹ́wàá (10) dín ní (-) Ọgọ́rin (80) ni Àádọ́rin (70) jẹ́.

This means that 80 – 10 = 70. Èyí túnmọ̀ sí wípé 80 – 10 = 70.
Apply addition (+) from 71 to 74

 Lo àfikún (+) láti 71 sí 74

71 - Seventy-one

 71 - Oókànléláàádọ́rin

72 - Seventy-two

 72 - Eéjìléláàádọ́rin

73 - Seventy-three

 73 - Ẹẹ́tàléláàádọ́rin

74 - Seventy-four 74 - Ẹẹ́rìnléláàádọ́rin  
Apply subtraction (-) from 75 to 79

 Lo ìyọkúrò (-) láti 75 sí 79

75 - Seventy-five

 75 - Aárùndínlọ́gọ́rin

76 - Seventy-six

 76 - Ẹẹ́rìndínlọ́gọ́rin

77 - Seventy-seven

 77 - Ẹẹ́tàdínlọ́gọ́rin

78 - Seventy-eight

 78 - Eéjìdínlọ́gọ́rin

79 - Seventy-nine

 79 – Oókàndínlọ́gọ́rin

80 - Eighty

 80 – Ọgọ́rin (20 x 4)

Note:

Ọgọ́rin (80) is a contraction of ogún mẹ́rin (20 x 4).

 Kíyèsí:

Ìsúnkì Ogún mẹ́rin (20 x 4) ni Ọgọ́rin (80) jẹ́.

Apply addition (+) from 81 to 84

 Lo àfikún (+) láti 81 sí 84

81 - Eighty-one
 
81 – Oókànlélọ́gọ́rin
82 - Eighty-two

 82 - Eéjìlélọ́gọ́rin

83 - Eighty-three

 83 - Ẹẹ́tàlélọ́gọ́rin

84 - Eighty-four

 84 - Ẹẹ́rìnlélọ́gọ́rin

Apply subtraction (-) from 85 to 89

 Lo ìyọkúrò (-) láti 85 sí 89

85 - Eighty-five

 85 - Aárùndínláàádọ́rùn-ún

86 - Eighty-six 86 - Ẹẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún
87 - Eighty-seven

 87 - Ẹẹ́tàdínláàádọ́rùn-ún

88 - Eighty-eight

 88 – Eéjìdínláàádọ́rùn-ún

89 - Eighty-nine

 89 – Oókàndínláàádọ́rùn-ún

90 - Ninety

 90 - Aádọ́rùn-ún (100 - 10)

Note:

Aádọ́rùn-ún (90) is a contraction of ẹẹ́wàá (10) dín ní (-/minus) Ọgọ́rùn-ún (100).

Kíyèsí:

Ìsúnkì ẹẹ́wàá (10) dín ní (-) Ọgọ́rùn-ún (100) ni Aádọ́rùn-ún (90) jẹ́.

This means that 100 – 10 = 90.

 Èyí túnmọ̀ sí wípé 100 – 10 = 90.

Apply addition (+) from 91 to 94 Lo àfikún (+) láti 91 sí 94
91 - Ninety-one
 
91 – Oókànléláàádọ́rùn-ún
92 - Ninety-two 92 - Eéjìléláàádọ́rùn-ún
93 - Ninety-three

 93 – Ẹẹ́tàléláàádọ́rùn-ún

94 - Ninety-four 94 - Ẹẹ́rìnléláàádọ́rùn-ún  
Apply subtraction (-) from 95 to 99

 Lo ìyọkúrò (-) láti 95 sí 99

95 - Ninety-five 95 - Aárùndínlọ́gọ́rùn-ún
96 - Ninety-six 96 - Ẹẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún
97 - Ninety-seven

 97 - Ẹẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún

98 - Ninety-eight 98 - Eéjìdínlọ́gọ́rùn-ún
99 - Ninety-nine 99 - Oókàndínlọ́gọ́rùn-ún
100 - One hundred

 100 - Ọgọ́rùn-ún (20 x 5)

Note:

Ọgọ́rùn-ún (100) is a contraction of ogún márùn-ún (20 x 5).

 Kíyèsí:

Ìsúnkì Ogún márùn-ún (20 x 5) ni Ọgọ́rùn-ún (100) jẹ́.

Tens

10 - Ten

20 - Twenty

30 - Thirty

40 - Forty

50 - Fifty

60 - Sixty

70 - Seventy

80 - Eighty

90 – Ninety

100 - One hundred

Àwọn òònkà Ẹẹ́wàá

10 - Ẹẹ́wàá

20 - Ogún

30 - Ọgbọ̀n

40 - Ogójì

50 - Àádọ́ta

60 - Ọgọ́ta

70 - Àádọ́rin

80 - Ọgọ́rin

90 - Aádọ́rùn-ún

100 - Ọgọ́rùn-ún

Mark as read

Privacy policy Terms of service
Contact us
Alteerlingual © 2023