Use your preferred language to learn new language
Ordinal number |
Nọ́mbà ipò déédé |
An ordinal number is a number that we use to tell of the position that something or a person is on a particular list. |
Nọ́mbà ipò déédé ni nọ́mbà tí a máa ń lò láti fi sọ ipò tí nǹkan tàbí ènìyàn wà ní inú àtòjọ kan ní pàtó. |
Note: In Yorùbá language, there are two different versions of the numbers used to tell of a position of something or a person on a list.. |
Kíyèsí: Ní èdè Yorùbá, àwọn nọ́mbà tí à ń lò láti fi sọ ipò tí nǹkan tàbí ènìyàn wà ní inú àtòjọ pín sí ẹ̀yà méjì. |
1. Ordinal numbers are written as shown below when they appear alone or after other parts of speech except a noun.
Ìkíní (first) Ìkejì (second) Ìkẹta (third) Ìkẹrin (fourth) Ìkarùn-ún (fifth), Ìkẹfà (sixth) and so on. |
1. Bí a ṣe fi hàn ní ìsàlẹ̀ yìí ni a ṣe máa ń kọ àwọn nọ́mbà ipò déédé tí wọ́n bá dá dúró tàbi tí wọ́n bá fi ara hàn lẹ́yìn àwọn ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ òmíràn àyàfi ọ̀rọ̀-orúkọ.
Ìkíní Ìkejì Ìkẹta Ìkẹrin Ìkarùn-ún Ìkẹfà àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. |
2. An ordinal number loses their first letter when they appear after a noun.
For example: táàmù kìn-ín-ní (first term) ẹni kejì (the second person) ilà kẹta (the third line) ilé kẹrin (the fourth house) ilé karùn-ún (the fifth time) and so on. |
2. Nọ́mbà ipò déédé máa ń pàdánù lẹ́tà àkọ́kọ́ wọn tí wọ́n bá fi ara hàn lẹ́yìn ọ̀rọ̀-orúkọ.
Fún àpẹrẹ: táàmù kìn-ín-ní ẹni kejì ilà kẹta ilé kẹrin ilé karùn-ún àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ́. |
Ordinal numbers with examples of how they are used in simple sentence. |
Àwọn nọ́mbà ipò déédé pẹ̀lú àpẹrẹ bí a ṣe ń lò wọ́n ní inú gbólóhùn kéékèèké. |
First
This is the first. First term. |
Ìkíní Kìn-ín-ní
Ìkíní rèé. Táàmù kìn-ín-ní. |
Second
Second term examination. |
Ìkejì Kejì
Ìdánwò táàmù kejì. |
Third
Third term examination. |
Ìkẹta Kẹta
Ìdánwò táàmù kẹta. |
Fourth
Fourth position. |
Ìkẹrin Kẹrin
Ipò kẹrin. |
Fifth
The fifth house on that street. |
Ìkarùn-ún Karùn-ún
Ilé kárùn-ún ní òpópónà yẹn. |
Sixth
The sixth book. |
Ìkẹfà Kẹfà
Ìwé kẹfà. |
Seventh
Seventh turn to your left. |
Ìkeje Keje
Ìyànà keje sí apá òsì rẹ. |
Eight
The eight turn to your right. |
Ìkẹjọ Kẹjọ
Ìyànà kẹjọ sí apá ọ̀tún rẹ |
Ninth
The ninth number. |
Ìkẹsàn-án Kẹsàn-án
Nọ́mbà kẹsàn-án. |
Tenth
The tenth number. |
Ìkẹwàá Kẹwàá
Nọ́mbà kẹwàá. |
Eleventh
The eleventh day. |
Ìkankànlá Kankànlá
Ọjọ́ kankànlá. |
Twelfth
The twelfth month. |
Ìkejìlá Kejìlá
Òṣù kejìlá. |
Thirteenth
The thirteenth year. |
Ìkẹtàlá Kẹtàlá
Ọdún kẹtàlá. |
Fourteenth
My fourteenth birthday. |
Ìkẹrìnlá Kẹrìnlá
Ọjọ́ ìbí kẹrìnlá mi. |
Fifteenth
The fifteenth building. |
Ìkarùndínlógún Karùndínlógún
Ilé karùndínlógún. |
Sixteenth
The sixteenth person. |
Ìkẹrìndínlógún Kẹrìndínlógún
Ẹni kẹrìndínlógún. |
Seventeenth
The seventeenth line. |
Ìkẹtàdínlógún Kẹtàdínlógún
Ilà kẹtàdínlógún. |
Eighteenth
The eighteenth time. |
Ìkejìdínlógún Kejìdínlógún
Ìgbà kejìdínlógún. |
Nineteenth
The nineteenth house. |
Ìkankàndínlógún Kankàndínlógún
Ilé kankàndínlógún. |
Twentieth
The twentieth position. |
Ogún
Ogún ipò. |
Twenty-first
Twenty-first year. |
Ìkankànlélógún Kankànlélógún
Ọdún kankànlélógún. |
Twnety-second
Twnety-second year. |
Ìkejìlélógún Kejìlélógún
Ọdún kejìlélógún. |
Twnety-third
Twnety-third year. |
Ìkẹtàlélógún Kẹtàlélógún
Ọdún kẹtàlélógún. |
Twnety-fourth
Twnety-fourth year. |
Ìkẹrìnlélógún Kẹrìnlélógún
Ọdún kẹrìnlélógún. |
Twnety-fifth
Twnety-fifth year. |
Ìkarùndínlọ́gbọ̀n Karùndínlọ́gbọ̀n
Ọdún karùndínlọ́gbọ̀n. |
Twnety-sixth
Twnety-sixth year. |
Ìkẹrìndínlọ́gbọ̀n Kẹrìndínlọ́gbọ̀n
Ọdún kẹrìndínlọ́gbọ̀n. |
Twnety-seventh
Twnety-seventh year. |
Ìkẹtàdínlọ́gbọ̀n Kẹtàdínlọ́gbọ̀n
Ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n. |
Twnety-eight
Twnety-eight year. |
Ìkejìdínlọ́gbọ̀n Kejìdínlọ́gbọ̀n
Ọdún kejìdínlọ́gbọ̀n. |
Twnety-ninth
Twnety-ninth year. |
Ìkankàndínlọ́gbọ̀n Kankàndínlọ́gbọ̀n
Ọdún kankàndínlọ́gbọ̀n. |
Thirtieth
Thirtieth year. |
Ọgbọ̀n
Ọgbọ̀n ọdún. |
Thirty-first
Thirty-first year. |
Ìkankànlélọ́gbọ̀n Kankànlélọ́gbọ̀n
Ọdún kankànlélọ́gbọ̀n. |
Thirty-second
Thirty-second birthday. |
Ìkejìlélọ́gbọ̀n Kejìlélọ́gbọ̀n
Ọjọ́-ìbí kejìlélọ́gbọ̀n. |
Thirty-third
Thirty-third birthday. |
Ìkẹtàlélọ́gbọ̀n Kẹtàlélọ́gbọ̀n
Ọjọ́-ìbí kẹtàlélọ́gbọ̀n. |
Thirty-fourth
Thirty-fourth birthday. |
Ìkẹrìnlélọ́gbọ̀n Kẹrìnlélọ́gbọ̀n
Ọjọ́-ìbí kẹrìnlélọ́gbọ̀n. |
Thirty-fifth
Thirty-fifth birthday. |
Ìkarùndínlógójì Karùndínlógójì
Ọjọ́-ìbí karùndínlógójì. |
Thirty-sixth
Thirty-sixth birthday. |
Ìkẹrìndínlógójì Kẹrìndínlógójì
Ọjọ́-ìbí kẹrìndínlógójì. |
Thirty-seventh
Thirty-seventh birthday. |
Ìkẹtàdínlógójì Kẹtàdínlógójì
Ọjọ́-ìbí kẹtàdínlógójì. |
Thirty-eight
Thirty-eight birthday. |
Ìkejìdínlógójì Kejìdínlógójì
Ọjọ́-ìbí kejìdínlógójì. |
Thirty-ninth
Thirty-ninth birthday. |
Ìkankàndínlógójì Kankàndínlógójì
Ọjọ́-ìbí kankàndínlógójì. |
Fortieth
The Fortieth day. |
Ogójì
Ogójì ọjọ́. |
Forty-first
Forty-first month. |
Ìkankànlélógójì Kankànlélógójì
Oṣù kankànlélógójì. |
Forty-second
Forty-second month. |
Ìkejìlélógójì Kejìlélógójì
Oṣù kejìlélógójì. |
Forty-third
Forty-third month. |
Ìkẹtàlélógójì Kẹtàlélógójì
Oṣù kẹtàlélógójì. |
Forty-fourth
Forty-fourth month. |
Ìkẹrìnlélógójì Kẹrìnlélógójì
Oṣù kẹrìnlélógójì. |
Forty-fifth
Forty-fifth month. |
Ìkarùndínláàádọ́ta Karùndínláàádọ́ta
Oṣù karùndínláàádọ́ta. |
Forty-sixth
Forty-sixth month. |
Ìkẹrìndínláàádọ́ta Kẹrìndínláàádọ́ta
Oṣù kẹrìndínláàádọ́ta. |
Forty-seventh
Forty-seventh month. |
Ìkẹtàdínláàádọ́ta Kẹtàdínláàádọ́ta
Oṣù kẹtàdínláàádọ́ta. |
Forty-eight
Forty-eight month. |
Ìkejìdínláàádọ́ta Kejìdínláàádọ́ta
Oṣù kejìdínláàádọ́ta. |
Forty-ninth
Forty-ninth month. |
Ìkankàndínláàádọ́ta Kankàndínláàádọ́ta
Oṣù kankàndínláàádọ́ta. |
Fiftieth
Fiftieth month. |
Àádọ́ta
Àádọ́ta oṣù. |
Fifty-first
Fifty-first week. |
Ìkankànléláàádọ́ta Kankànléláàádọ́ta
Ọ̀sẹ̀ kankànléláàádọ́ta. |
Fifty-second
Fifty-second week. |
Ìkejìléláàádọ́ta Kejìléláàádọ́ta
Ọ̀sẹ̀ kejìléláàádọ́ta. |
Fifty-third
Fifty-third week. |
Ìkẹtàléláàádọ́ta Kẹtàléláàádọ́ta
Ọ̀sẹ̀ kẹtàléláàádọ́ta. |
Fifty-fourth
Fifty-fourth week. |
Ìkẹrìnléláàádọ́ta Kẹrìnléláàádọ́ta
Ọ̀sẹ̀ kẹrìnléláàádọ́ta. |
Fifty-fifth
Fifty-fifth week |
Ìkarùndínlọ́gọ́ta Karùndínlọ́gọ́ta
Ọ̀sẹ̀ karùndínlọ́gọ́ta. |
Fifty-sixth
Fifty-sixth week. |
Ìkẹrìndínlọ́gọ́ta Kẹrìndínlọ́gọ́ta
Ọ̀sẹ̀ kẹrìndínlọ́gọ́ta. |
Fifty-seventh
Fifty-seventh week. |
Ìkẹtàdínlọ́gọ́ta Kẹtàdínlọ́gọ́ta
Ọ̀sẹ̀ kẹtàdínlọ́gọ́ta. |
Fifty-eight
Fifty-eight week. |
Ìkejìdínlọ́gọ́ta Kejìdínlọ́gọ́ta
Ọ̀sẹ̀ kejìdínlọ́gọ́ta. |
Fifty-ninth
Fifty-ninth week. |
Ìkakàndínlọ́gọ́ta Kakàndínlọ́gọ́ta
Ọ̀sẹ̀ kakàndínlọ́gọ́ta. |
Sixtieth
Sixtieth week. |
Ọgọ́ta
Ọgọ́ta ọ̀sẹ̀, |
Sixty-first
Sixty-first day. |
Ìkankànlélọ́gọ́ta Kankànlélọ́gọ́ta
Ọjọ́ kankànlélọ́gọ́ta. |
Sixty-second
Sixty-second day. |
Ìkejìlélọ́gọ́ta Kejìlélọ́gọ́ta
Ọjọ́ kejìlélọ́gọ́ta. |
Sixty-third
Sixty-third day. |
Ìkẹtàlélọ́gọ́ta Kẹtàlélọ́gọ́ta
Ọjọ́ kẹtàlélọ́gọ́ta. |
Sixty-fourth
Sixty-fourth day. |
Ìkẹrìnlélọ́gọ́ta Kẹrìnlélọ́gọ́ta
Ọjọ́ kẹrìnlélọ́gọ́ta. |
Sixty-fifth
Sixty-fifth day. |
Ìkarùndínláàádọ́rin Karùndínláàádọ́rin
Ọjọ́ karùndínláàádọ́rin. |
Sixty-sixth
Sixty-sixth day. |
Ìkẹrìndínláàádọ́rin Kẹrìndínláàádọ́rin
Ọjọ́ kẹrìndínláàádọ́rin. |
Sixty-seventh
Sixty-seventh day. |
Ìkẹtàdínláàádọ́rin Kẹtàdínláàádọ́rin
Ọjọ́ kẹtàdínláàádọ́rin. |
Sixty-eight
Sixty-eight day. |
Ìkejìdínláàádọ́rin Kejìdínláàádọ́rin
Ọjọ́ kejìdínláàádọ́rin. |
Sixty-ninth
Sixty-ninth day. |
Ìkankàndínláàádọ́rin Kankàndínláàádọ́rin
Ọjọ́ kankàndínláàádọ́rin. |
Seventieth
Seventieth day. |
Àádọ́rin
Àádọ́rin ọjọ́. |
Seventy-first
Seventy-first book. |
Ìkankànléláàádọ́rin Kankànléláàádọ́rin
Ìwé kankànléláàádọ́rin. |
Seventy-second
Seventy-second book. |
Ìkejìléláàádọ́rin Kejìléláàádọ́rin
Ìwé kejìléláàádọ́rin. |
Seventy-third
Seventy-third book. |
Ìkẹtàléláàádọ́rin Kẹtàléláàádọ́rin
Ìwé kẹtàléláàádọ́rin. |
Seventy-fourth
Seventy-fourth book. |
Ìkẹrìnléláàádọ́rin Kẹrìnléláàádọ́rin
Ìwé kẹrìnléláàádọ́rin. |
Seventy-fifth
Seventy-fifth book. |
Ìkarùndínlọgọ́rin Karùndínlọgọ́rin
Ìwé karùndínlọgọ́rin. |
Seventy-sixth
Seventy-sixth page. |
Ìkẹrìndínlọ́gọ́rin Kẹrìndínlọ́gọ́rin
Ojú-ìwé kẹrìndínlọ́gọ́rin. |
Seventy-seventh
Seventy-seventh page. |
Ìkẹtàdínlọ́gọ́rin Kẹtàdínlọ́gọ́rin
Ojú-ìwé kẹtàdínlọ́gọ́rin. |
Seventy-eight
Seventy-eight page. |
Ìkejìdínlọ́gọ́rin Kejìdínlọ́gọ́rin
Ojú-ìwé kejìdínlọ́gọ́rin. |
Seventy-ninth
Seventy-ninth page. |
Ìkankàndínlọ́gọ́rin Kankàndínlọ́gọ́rin
Ojú-ìwé kankàndínlọ́gọ́rin. |
Eightieth
Eightieth time. |
Ọgọ́rin
Ọgọ́rin ìgbà. |
Eighty-first
Eighty-first day. |
Ìkankànlélọ́gọ́rin Kankànlélọ́gọ́rin
Ọjọ́ kankànlélọ́gọ́rin. |
Eighty-second
Eighty-second day. |
Ìkejìlélọ́gọ́rin Kejìlélọ́gọ́rin
Ọjọ́ kejìlélọ́gọ́rin. |
Eighty-third
Eighty-third day. |
Ìkẹtàlélọ́gọ́rin Kẹtàlélọ́gọ́rin
Ọjọ́ kẹtàlélọ́gọ́rin. |
Eighty-fourth
Eighty-fourth day. |
Ìkẹrìnlélọ́gọ́rin Kẹrìnlélọ́gọ́rin
Ọjọ́ kẹrìnlélọ́gọ́rin. |
Eighty-fifth
Eighty-fifth day. |
Ìkarùndínláàádọ́rùn-ún Karùndínláàádọ́rùn-ún
Ọjọ́ karùndínláàádọ́rùn-ún. |
Eighty-sixth
Eighty-sixth day. |
Ìkẹrìndínláàádọ́rùn-ún Kẹrìndínláàádọ́rùn-ún
Ọjọ́ kẹrìndínláàádọ́rùn-ún. |
Eighty-seventh
Eighty-seventh day. |
Ìkẹtàdínláàádọ́rùn-ún Kẹtàdínláàádọ́rùn-ún
Ọjọ́ kẹtàdínláàádọ́rùn-ún. |
Eighty-eight
Eighty-eight day. |
Ìkejìdínláàádọ́rùn-ún Kejìdínláàádọ́rùn-ún
Ọjọ́ kejìdínláàádọ́rùn-ún. |
Eighty-ninth
Eighty-ninth day. |
Ìkankàndínláàádọ́rùn-ún Kankàndínláàádọ́rùn-ún
Ọjọ́ kankàndínláàádọ́rùn-ún. |
Ninetieth
Ninetieth day. |
Àádọ́rùn-ún
Àádọ́rùn-ún ọjọ́. |
Ninety-first
Ninety-first anniversary. |
Ìkankànléláàádọ́rùn-ún Kankànléláàádọ́rùn-ún
Àjọ̀dún kankànléláàádọ́rùn-ún. |
Ninety-second
Ninety-second anniversary. |
Ìkejìléláàádọ́rùn-ún Kejìléláàádọ́rùn-ún
Àjọ̀dún kejìléláàádọ́rùn-ún. |
Ninety-third
Ninety-third anniversary. |
Ìkẹtàléláàádọ́rùn-ún Kẹtàléláàádọ́rùn-ún
Àjọ̀dún kẹtàléláàádọ́rùn-ún. |
Ninety-fourth
Ninety-fourth anniversary. |
Ìkẹrìnléláàádọ́rùn-ún Kẹrìnléláàádọ́rùn-ún
Àjọ̀dún kẹrìnléláàádọ́rùn-ún. |
Ninety-fifth
Ninety-fifth anniversary. |
Ìkarùndínlọ́gọ́rùn-ún Karùndínlọ́gọ́rùn-ún
Àjọ̀dún karùndínlọ́gọ́rùn-ún. |
Ninety-sixth
Ninety-sixth anniversary. |
Ìkẹrìndínlọ́gọ́rùn-ún Kẹrìndínlọ́gọ́rùn-ún
Àjọ̀dún kẹrìndínlọ́gọ́rùn-ún. |
Ninety-seventh
Ninety-seventh anniversary. |
Ìkẹtàdínlọ́gọ́rùn-ún Kẹtàdínlọ́gọ́rùn-ún
Àjọ̀dún kẹtàdínlọ́gọ́rùn-ún. |
Ninety-eight
Ninety-eight anniversary. |
Ìkejìdínlọ́gọ́rùn-ún Kejìdínlọ́gọ́rùn-ún
Àjọ̀dún kejìdínlọ́gọ́rùn-ún. |
Ninety-ninth
Ninety-ninth anniversary. |
Ìkankàndínlọ́gọ́rùn-ún Kankàndínlọ́gọ́rùn-ún
Àjọ̀dún kankàndínlọ́gọ́rùn-ún. |
Hundredth
Hundredth year. |
Ọgọ́rùn-ún
Ọgọ́rùn-ún ọdún. |
Privacy policy
•
Terms of service
Contact us
Alteerlingual © 2023