Use your preferred language to learn new language
Time telling |
Sísọ àkókò |
Units of time
|
Àwọn ẹ̀yà ara àkókò
|
Note:
|
Kíyèsí:
|
There are two ways of telling time.
|
Ọ̀nà oríṣi méjì ni a le gbà sọ àkókò.
|
Telling the 12-hour time |
Sísọ àkókò wákàtí méjìlá |
There are 24 hours in a day. |
Wákàtí mẹ́rìnlélógún ni ó wà ní inú ọjọ́ kan. |
The 12-hour time counts from the first hour (1) to the twelfth hour (12) twice to make one (1) day.
The first count of twelve is for hours between midnight/morning (am) and noon.
The second count of twelve is for hours between noon and midnight (pm).
|
Àkókò wákàtí méjìlá máa ń ka ìgbà láti orí wákàtí kíní (1) títí dé orí wákàtí kejìlá (12) ní ẹ̀mejì láti jẹ́ ọjọ́ kan.
Òònkà wákàtí méjìlá àkọ́kọ́ wà fún àkókò tí ó wà láti agbede méjì òru títí dé agogo méjìlá ọ̀sán gangan.
Òònkà wákàtí méjìlá kejì wà fún àkókò tí ó wà láti agogo méjìlá ọ̀sán gangan títí dé agbede méjìlá òru.
|
In the 12-hour time, the day starts at 12:00am (midnight) and ends at 11:59pm. |
Agogo méjìlá òru (12:00am) ni ọjọ́ máa ń bẹ̀rẹ̀ ní inú àkókò wákàtí méjìlá, á sì pin ní agogo méjìlá òru ku ìṣẹ́jú kan (11:59pm). |
AM (Ante meridiem) refers to the period of the day between midnight (12:00am) and noon/midday (11:59am). |
AM tọ́ka sí àkókò inú ọjọ́ tí ó wà ní àárín agogo méjìlá òru (12:00am) àti ọ̀sán gangan (11:59am). |
PM (Post meridiem) refers to the period of the day between noon/midday (12:00pm) and midnight (11:59pm).
|
PM tọ́ka sí àkókò inú ọjọ́ tí ó wà ní àárín agogo méjìlá ọ̀sán gangan (12:00pm) àti agogo méjìlá òru (11:59pm).
|
Privacy policy
•
Terms of service
Contact us
Alteerlingual © 2023