Use your preferred language to learn new language
Hands of the clock |
Àwọn ọwọ́ agogo |
A clock has three (3) hands. |
Ọwọ́ mẹ́ta (3) ni agogo ní. |
The three (3) hands of the clock are: a. The seconds hand
The seconds hand is the thinnest of the three hands. The seconds hand moves fastest among the three hands. |
Àwọn ọwọ́ mẹ́ta tí agogo ní náà ni: a. Ọwọ́ ìṣẹ́jú-àáyá
Ọwọ́ ìṣẹ́jú-àáyá ni ó tínrín jù láàrín àwọn ọwọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Ọwọ́ ìṣẹ́jú-àáyá ni ó yára jù lọ láàrín àwọn ọwọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. |
b. The minutes hand
The minutes hand is as long as the seconds hand but thicker than seconds hand.
The minutes hand moves slower that the seconds hand but faster than the hour hands. |
b. Ọwọ́ ìṣẹ́jú
Ọwọ́ ìṣẹ́jú gùn bíi ọwọ́ ìṣẹ́jú-àáyá ṣùgbọ́n ó sanra ju ọwọ́ ìṣẹ́jú-àáyá lọ.
Ọwọ́ ìṣẹ́jú kò yára bíi ọwọ́ ìṣẹ́jú-àáyá ṣùgbọ́n ó yára ju ọwọ́ wákàtí lọ. |
c. The hours hand The hours hand is the thickest of the three (3) hands. The hours hand is the shortest of the three (3) hands. |
c. Ọwọ́ wákàtí Ọwọ́ wákàtí ni ó sanra jù láàrín àwọn ọwọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Ọwọ́ wákàtí ni ó sì kúrú jù láàrín àwọn ọwọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. |
Privacy policy
•
Terms of service
Contact us
Alteerlingual © 2023