Use your preferred language to learn new language
Time telling guidelines |
Àwọn ìlànà nípa sísọ àkókò |
60 seconds make 1 minute. |
Ogọ́ta ìṣẹ́jú-àáyá jẹ́ ìṣẹ́jú kan. |
60 minutes make 1 hour. |
Ọgọ́ta ìṣẹ́jú jẹ́ wákàtí kan. |
24 hours make 1 day. |
Wákàtí mẹ́rìnlélógún jẹ́ ọjọ́ kan. |
![]() |
![]() |
1. The seconds hand moves five (5) times from one number to another. |
1. Ìgbà ẹ̀márùn-ún ni ọwọ́ ìṣẹ́jú-àáyá máa ń sún láti orí nọ́mbà kan sí ìkejì. |
2. For example, the seconds hand moves five (5) times between twelve (12) and one (1), another five (5) times between one (1) and two (2), and so on. |
2. Fún àpẹrẹ, ìgbà ẹ̀márùn-ún ni ọwọ́ ìṣẹ́jú-àáyá máa sún láàrín eéjìlá (12) àti oókan (1), á tún sún ní ẹ̀márùn-ún òmíràn láàrín oókan (1) àti eéjì (2), àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. |
3. Altogether, the seconds hand moves 60 times from twelve (12) to twelve (12) to count 1 minutes. |
3. Ní àpapọ̀, láti ka ìṣẹ́jú kan, ọgọ́ta ìgbà ni ọwọ́ ìṣẹ́jú-àáyá máa sún láti orí eéjìlá (12) títí padà sí orí eéjìlá (12). |
4. The minutes hand also moves five (5) times between two (2) number. |
4. Ìgbà ẹ̀márùn-ún (5) náà ni ọwọ́ ìṣẹ́jú máa ń sún láti nọ́mbà kan sí ìkejì. |
5. For example, the minutes hand moves five (5) times from twelve (12) and one (1), another five (5) times between one (1) and two (2), and so on. |
5. Fún àpẹrẹ, ìgbà ẹ̀márùn-ún ni ọwọ́ ìṣẹ́jú máa sún láàrín nọ́mbà eéjìlá (12) àti oókan (1), á tún sún ní ẹ̀márùn-ún (5) òmíràn láàrín oókan (1) àti eéjì (2) àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. |
6. Altogether, the minutes hand moves 60 times from 12 to 12 to count 1 hour. |
6. Ní àpapọ̀, láti ka wákàtí kan, ọgọ́ta ìgbà ni ọwọ́ ìṣẹ́jú máa sún láti nọ́mbà eéjìlá (12) títí padà sí orí nọ́mbà eéjìlá (12). |
7. The hours hand shifts slowly from one number to another. |
7. Díẹ̀-díẹ̀ láì yára ni ọwọ́ wákàtí máa ń sún láti nọ́mbà kan sí ìkejì. |
8. When the hours hand moves completely from one number to another number, it means 1 hour has gone by. |
8. Tí ọwọ́ wákàtí bá sún pátápátá láti orí nọ́mbà kan sí ìkejì, èyí túnmọ̀ sí wípé wákàtí kan ti kọjá. |
9. Altogether, the hours hand moves 24 times to count 24 hours for a day. |
9. Ní àpapọ̀, ìgbà mẹ́rìnlélógún ni ọwọ́ wákàtí máa ń sún láti ka wákàtí mẹ́rìnlélógún fún ọjọ́ kan. |
10. Except it is reading a perfect time like 12:00 or 5:00 or 10:00 and so on, the hours hand is many times found in-between two numbers. |
10. Ní àimọye ìgbà, àárín nọ́mbà méjì ni ọwọ́ wákàtí máa ń wà àyàfi tí ó bá ń sọ àkókò pípé bíi agogo méjìlá (12:00) tàbí agogo márùn-ún (5:00) tàbí agogo mẹ́wàá (10:00) àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. |
|
|
B 11. When the hours hand is found in-between two numbers, it means the lowest number is the current hour. |
B 11. Tí ọwọ́ wákàtí bá bọ́ sí áàrín nọ́mbà méjì, èyí túnmọ̀ sí wípé nọ́mbà tí ó kéré jùlọ ni àkókò ń sọ lọ́wọ́lọ́wọ́. |
12. The time on the clock above is twenty minutes past three (3:20). |
12. Àkókò tí agogo tí ó wà ní òkè yíì ń tókàa sí ni agogo mẹ́ta kọjá ogún ìṣẹ́jú (3:20). |
13. When reading the minutes hand, the clock’s interface is usually divided into the left and the right parts. |
13. A máa ń pín ojú agogo sí apá òsì àti apá ọ̀tún ní ìgbàkígbà tí a bá ń ka ọwọ́ ìṣẹ́jú. |
14. When the minutes hand is on the left side, it means the number of minutes from the point of the minutes hand to number twelve (12) is what is left to reach the hour right after the hours hand at that time. |
14. Tí ọwọ́ ìṣẹ́jú bá wà ní apá òsì, èyí túnmọ̀ sí wípé nọ́mbà tí ó wà nì iwájú ọwọ́ wákàtí ní àkókò yẹn ku iye ìṣẹ́jú tí ó wà láàrín ibi tí ọwọ́ ìṣẹ́jú náà wà pẹ̀lú nọ́mbà eéjìlá (12). |
15. The time in the image above is thirteen minutes to five (4:47). |
15. Agogo máarùn-ún ku ìṣẹ́jú mẹ́tàlá (4:47) ni àkókò tí àwòrán agogo tí ó wà ní òkè yìí ń sọ. |
16. When the minutes hand is on the right side, it means the hour right before the hours hand at the time is past the number of minutes from number twelve (12) to the point of the minutes hand. |
16. Tí ọwọ́ ìṣẹ́jú bá wà ní apá ọ̀tún, èyí túnmọ̀ sí wípé iye ìṣẹ́jú tí ó wà láàrín nọ́mbà eéjìlá (12) àti ibi tí ọwọ́ ìṣẹ́jú náà wà ti kọjá nọ́mbà wákàtí tí ó wà nì ẹ̀yìn ọwọ́ wákàtí ní àkókò yẹn. |
17. The time as shown in the image above is nineteen minutes past five (5:19). |
17. Agogo máarùn-ún kọjá ìṣẹ́jú mọ́kàndínlógún (5:19) ni àkókò tí àwòrán agogo tí ó wà ní òkè yìí ń tọ́ka sí. |
Privacy policy
•
Terms of service
Contact us
Alteerlingual © 2023