Use your preferred language to learn new language
Telling time: the 24-hour time |
Sísọ àkókò wákàtí mẹ́rìnlélógún |
Remember that there are 24 hours in a day. |
Ṣe ìrántí wípé wákàtí mẹ́rìnlélógún (24) ni ó wà ní inú ọjọ́ kan. |
The 24-hour time counts all the 24 hours in a day consecutively from the first (1st) hour to the twenty-fourth (24th) hour. |
Àkókò wákàtí mẹ́rìnlélógún máa ń ka gbogbo wákàtí mẹ́rìnlélógún (24) tí ó wà ní inú ọjọ́ léraléra láti wákàtí kìn-ní-ní (1) títí dé wákàtí kẹrìnlélógún (24). |
In the 24-hour time, the day starts at 00:00hour (midnight) and ends at 23:59hours. |
Wákàtí oódo-oódo (00:00) agbede méjì òru ni ọjọ́ máa ń bẹ̀rẹ̀ ní inú àkókò wákàtí mẹ́rìnlélógún, á sì pin ní agogo mẹ́rìnlélógún ku ìṣẹ́jú kan (23:59). |
Clocks with 00:00 to 24:00 prints like the image above are common. |
Àwọn irúurú agogo tí ó ní òòntẹ̀ wákàtí 00:00 dé wákàtí 24:00 bí àwòrán tí ó wà ní òkè yìí ò wọ́npọ̀. |
The image below is an example of the type of 24-hour clock that is common. |
Àwòrán agogo tí ó wà ní ìsàlẹ̀ yìí ni àpẹrẹ agogo wákàtí mẹ́rìnlélógún tí ó wọ́npọ̀. |
The black numbers are read to tell the time from midnight to midday (00:00 to 12:00). |
Àwọn nọ́mbà dúdú ni a máa ń kà láti fí sọ àkókò láti agbede méjì òru dé agogo méjìlá ọ̀sán gangan (00:00 to 12:00). |
The red numbers are read to tell the time from midday to midnight (13:00 to 24:00). |
Àwọn nọ́mbà pupa ni a máa ń kà láti fí sọ àkókò láti agogo métàlá ọ̀sán dé agogo mẹ́rìnlélógún òru (13:00 to 24:00). |
For example, we can read the time on the images of the clocks below in two ways: |
Fún àpẹrẹ, a lè ka àkókò tí àwọn àwòrán agogo tí ó wà ni ìsàlè yìí ń tọ́ka sí ní ọ̀nà méjì: |
![]() ![]() |
![]() ![]() |
1. We may say the time is 01:00hour if the period of the day is after midnight. |
1. A lè sọ wípé agogo kan (01:00hour) òru ni ó lù tí àkókò ọjọ́ bá jẹ́ lẹ́yìn agbede méjì òru. |
2. We may also say the time is 13:00hours if the period of the day falls in the afternoon. |
2. A tún lè sọ wípé agogo mẹ́tàlá (13:00hour) ni ó lù tí àkókò ọjọ́ bá bọ́ sí ọ̀sán.
|
Privacy policy
•
Terms of service
Contact us
Alteerlingual © 2023